Numbers 6:22-26

Ìbùkún àlùfáà

22 Olúwa sọ fún Mose pé, 23“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ sọ fún wọn pé:

24“ ‘ “Kí Olúwa bùkún un yín
Kí ó sì pa yín mọ́.
25Olúwa kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára.
Kí ó sì ṣàánú fún un yín.
26Olúwa bojú wò yín;
Kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’
Copyright information for YorBMYO